BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Fídíò, Wo bí o ṣe lè gba nọ́mbà ìdánimọ̀ owó orí, TIN rẹ láì dàmú jìnnà
Nọmba idanimọ fun owo ori, TIN jẹ numba idanimọ fun amojuto eto sisan owo ori labẹ ofin owo ori tuntun ti ijọba Naijiria bẹrẹ lọjọ kinni oṣu kinni ọdun 2026.
Òfin owó orí tuntun bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Kínní ọdún 2026, èyí ni bí o ṣe lè gba nọ́mbà ìdánimọ̀ owó orí (Tax ID)
Ọpọ eeyan ni ọrọ nọmba yii ko ye, paapaa bijọba ṣe tun sọ pe o le ṣoro fun ẹni ti ko ba ni in lati le lo apo ikowosi rẹ, bẹrẹ lati ọjọ akọkọ ninu oṣu Kin-ni-ni ọdun 2026.
'Kò tíi ju wákàtí mẹ́fà tí Anthony Joshua wọ Nàìjíríà fún àbẹ̀wò ọdún tó fi ko ìjàmbá', àwọn ẹbí Anthony Joshua sọ̀rọ̀ lórí ipó ìlera rẹ̀
Alagba Adedamola sọ pe ibanujẹ ni ijamba ọkọ naa ko ba mọlẹbi Joshua, paapaa nitori iku awọn ọrẹ rẹ ti wọn jọ wa si Naijiria lati ṣọdun.
Èṣù tiwa kì i ṣe Sátánì, olùgbàlà aráyé ni -Àwọn Oníṣẹ́ṣe Ilẹ̀ Iwo.
Araba Awo ilu Iwo, Ifatayo Afolabi, ṣalaye fun BBC News Yoruba, pe Esu ti awọn Oniṣẹṣe n foribalẹ fun, yatọ si Satani ti awọn Kristẹni ati Musulumi gba pe ko daa.
Àwọn agbésùnmọ̀mí tó sá láti ìpínlẹ̀ Sokoto lẹ́yìn ìkọlù America kó sọ́wọ́ Àmọtẹ́kùn l'Ondo
Ikọ Amọtẹkun Ondo sọ pe lara awọn agbesunmomi ipinlẹ Sokoto ti wọn sa wa si igbo ọba ipinlẹ Ondo ni awọn eeyan yii.
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́, Duration 1,01
Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
INEC kéde orúkọ àwọn olùdíje fún ìbò Gómìnà Ekiti lọ́dún 2026, olùdíje fẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP kò sí níbẹ̀, ìdí rèé
Awọn oludije lati inu ẹgbẹ oṣelu mejila yii ni ajọ INEC ti ṣayẹwo fini fini lori wọn ko to gbe orukọ wọn jade.
Fídíò, 'Kí a tó kọ orin “Odun nlo sopin”, a ju ara wa sínú àdúrà, bíbélì, ìmísí, ...', Duration 8,23
Adari ẹgbẹ akọrin to kọrin ọdun n lọ sopin, Mama D.O Fasoyin ba BBC Yoruba sọrọ lori agbekalẹ orin naa.
Àwọn jàǹdùkú kọlu àwọn tó ń fẹ̀hónú hàn nítorí ìjínigbé nílé ìjọba Kwara
Gẹgẹ bí ẹni ti ọrọ naa soju rẹ ṣe ṣalaye fun BBC, iyẹn Ọgbẹni Ganiyu, o ni ile ijọba ipinlẹ Kwara gan-an ni wọn ti kọlu awọn olufẹhonu han naa.
Wọ́n lu adarí eré lálùkì, já a síhòhò níta gbangba, ìdí rèé
Don Pedro Obaseki jẹ aburo fun gomina ipinlẹ Edo tẹlẹ, Godwin Obaseki,ṣugbọn eyi ko nitumọ kankan loju awọn to lu u lalubami nita gbangba.
Ọ̀rọ̀ di gbas-gbos láàárín Makinde àti Fayose lórí ₦50bn tí Fayose ní Tinubu fún ìpínlẹ̀ Oyo lórí ìbúgbàmù Bodija n'Ibadan
Oladamọran gomina sọ pe Makinde ṣe ikede fun gbogbo eeyan lori owo iranwọ to rigba lati ọdọ ijọba apapọ ati bo ti gbe igbimọ kan dide lati ṣakoso lilo owo naa.
Ẹbí Allwell Ademola sọ̀rọ̀ lórí ikú rẹ̀ àti ìgbà tí ètò ìsìnkú lè wáyé
Ẹbi Ademola sọ ninu atẹjade ti Ọgbẹni Adegboyega Adebayo buwọ́lu pe àwọn ti gba fun Ọlọrun lori iku Allwell, bo tilẹ jẹ pe ọkan awọn gbọgbẹ.
Móríwú
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Tinubu fún Makinde ní N50bn owó ìrànwọ́ lásìkò ìbúgbàmù Bodija, èròńgbà rẹ̀ láti di ààrẹ ló ń pín PDP yẹ́lẹyẹ̀lẹ - Fayose
Ayodele Fayose sọrọ yii lori eto kan to waye nileeṣẹ tẹlifisan TVC niluu Eko.
"Kó tó di ọjọ́ Kérésì la ti fẹ́ yín àdó olóró mọ́ àwọn agbébọn, síbẹ̀, Amẹrika ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mú ẹyẹ bọ̀ lápò"
Ìkéde yìí jẹyọ nínú àtẹ̀jáde kan tí Akọwe ileeṣẹ ologun fún Amẹrika, Pete Hegseth, fi sójú òpó ayélujára rẹ̀.
Wo àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tíátà àti olórin tó kú ní 2025
Kanran, Asakoko, Sanku àti ọ̀pọ̀ amúlùdùn míràn wà lára àwọn amúlùdùn tí BBC News Yorùbá ṣe àkójọpọ̀ wọn nínú àwọn ènìyàn tó bá 2025 lọ.
Ayédèrú òṣìṣẹ́ aṣọ́bodè lu Soun Ogbomoso ní jìbìtì N39.5m, ọ̀rọ̀ di tilé ẹjọ́
Muhammed, ẹni ọdun marundinlaadọta (45) pe ara rẹ ni ọga aṣọbode ipinlẹ Oyo fun Kabiyesi Olaoye Ghandi láti gba owó tuulu lọ́wọ́ rẹ̀.
Wo àwọn ìbéèrè mẹ́fà tó yẹ kí o mọ ìdáhùn sí nípa ọdún Kérésìmesì
Lásìkò ọdún yìí ni àwọn Kristẹni máa ń ṣe àjọyọ̀ tó fi mọ́ wíwọ aṣọ tuntun, síse oúnjẹ aládùn, pínpín ẹ̀bùn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Àwọn afurasí ọmọ ẹgbẹ́ Yoruba Nation gbégi dínà, kọlu ọlọ́pàá lásìkò ọdún Kérésì, ọwọ́ tẹ mẹ́jọ lára wọn
Ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá ni agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Oluseyi Babaseyi nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde ti kéde ọ̀rọ̀ náà.
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Super Eagles pẹ̀lú Tunisia máa lágbára àmọ́ a máa borí wọn - Akọ́nimọ̀ọ́gbá àti Balogun Super Eagles sọ̀rọ̀ akin
Ọla ọjọ Abamẹta, ọjọ Kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila ọdun 2025 ni Tunisia yoo ma wọya ija pẹlu Naijiria, ni papa iṣere Fes, ni Morocco
Ìbúgbàmù Offa tó ba ilé àti sọ́ọ̀bù jẹ́, ṣe èèyàn léṣe kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìkọlù Amẹ́ríkà, ohun tó ṣokùnfà ìṣẹ̀lẹ̀ náà rèé
Ileeṣẹ ọlọ́pàá nipinlẹ Kwara tí sọ̀rọ̀ pé lootọ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ń wáyé, tí ìwádìí sì ń lọ lọ́wọ́ láti wádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Boxing Day: Kí ni ìdí tí wọ́n fi ń pe ọjọ́ kejì ọdún Kérésì ní Boxing Day?
Boxing Day ko ni nnkankan ṣe pẹlu ẹṣẹ kíkàn gẹgẹ bi awọn eeyan kan ṣe lero.
Táńkà epo gbiná lọ́jọ́ Kérésì, èèyàn méji kú ní márosẹ̀ Eko sí Badagry
'Lagos State Traffic Management Authority' (LASTMA) to n ri si igbokegbodo ọkọ niluu Eko, fidi ijamba naa mulẹ.
Ìjà àgbà méjì bẹ̀rẹ̀ láàrin Abubakar Malami àti EFCC, bó ṣe ń jẹ́jọ́ ẹ̀sùn kíkó dúkìá tó tó N212bn lọ́nà èrú jọ
Awọn ile olowo nla ati ileeṣẹ to kuro ni wasa ni EFCC sọ pe Malami ko jọ ni ilu Abuja, Kano ati Kebbi.
Kí ló ń jẹ́ Eyo, níbo ló ti wá sílú Eko, àwọn wo ló ń gbé e, kí sì ni èèwọ̀ rẹ̀?
Bí àṣekágbá ọdún Eyo ṣe ń wáyé lónìí, BBC News Yorùbá ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn nípa ohun tí ọdún Eyo dá lé lórí.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ọba alayé tí wọ́n jí gbé ní Kwara gba ìtúsílẹ̀
Agbẹnusọ ilu naa, Ayinla Lawal, fidi ẹ mulẹ pe Ọba Kamilu Salami ti kuro ni akata ajinigbe.
Ọlọ́pàá tó tẹ̀lé Akpabio wá síbi oyè Seyi Tinubu àti Yari ko àgbákò ikú òjijì bí ọkọ̀ agbepo ṣe tẹ̀ ẹ́ lórí mọ́lẹ̀ n'Ibadan
Ààrẹ ilé aṣòfin àgbà fúnra rẹ lo kéde ìṣẹ̀lẹ̀ yìí níbi ìjókòó ilé aṣòfin àpapọ̀ to wáyé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun ana.
Ìtàn rèé nípa bí ikú Bola Ige ṣe ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọdún 24 tó jáde láyé, láì mú ẹni tó pa á
Bó ṣe pé ọdún mẹ́rìnlélógún tí àgbà Amòfin Bola Ige jáde láyé, BBC News Yorùbá ṣe àkójọpọ̀ ìtàn àwọn agbébọn ṣe pa á àti kókó ohun tó gbé ṣe nígbà ayé rẹ̀.
Wasiu Ayinde kéde pé òun kò du ipò Awujalẹ mọ́ lẹ́yìn tó lulẹ̀ lórí ẹjọ tó pé tako ìgbésẹ̀ yíyan Awujale tuntun
Adajọ A. A. Omoniyi da ẹjọ́ Wasiu Ayinde nù lórí àwíjàre pé ẹjọ́ náà k o lẹsẹ nilẹ ati pe ko si ẹri to dantọ lati gbe ẹbẹ naa lẹyin.
Kéré ó! Májèlé tó léwu fún àgọ́ ara ni oúnjẹ 'Indomie Vegetable Flavour', a ti ń kó o kúrò lọ́jà – NAFDAC kìlọ̀
Ọ̀gá agba ajọ NAFDAC, Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye Indomie ọhun ko wa lode fun tita ni Naijiria lásìkò yii nitori orilẹede France ni wọn ti n pese rẹ.
Àlàyé rèé lórí bí nọ́mbà NIN àti ìwé ẹ̀rí CAC ṣe le rọ́pò nọmbà owó orí rẹ lọ́dún tuntun
FIRS ni awọn ti kii pa owo wọle bii awọn akẹkọọ atawọn ti wọn ṣi wa labẹ obi tabi alagbatọ wọn ko nilo Tax ID kankan.
Wo awọn ìjọ ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ tí kì í ṣe ọdún Kérésìmesì
Gẹgẹ bi igbagbọ awọn ẹlẹsin Kristi, ọdun Keresimesi n ṣami ìbí Jesu olugbala ni, ẹni ti a gbọ pe wọn bi si ibujẹ ẹran ni ilu Bethlehem, ti ìbí rẹ si yatọ, to jẹ mimọ lati ode ọrun.
Ìjàmbá iná jó ilé ìtajà lọ́jà Balogun l'Eko lọ́dún Kérésì ku ọ̀la, ọ̀pọ̀ dúkìá ṣófò
Àtẹ̀jáde tí àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko ìyẹn Lagos State Emergency Management Agency, LASEMA ṣe sọ, wọ́n ní àjà kẹrin ni iná náà ti dédé ṣẹ́yọ.
Àwọn ẹ̀bùn mẹ́wàá tí o lè fún àwọn èèyàn lásìkò Kérésìmesì láì pa àpò rẹ lára
BBC News Yorùbá ṣe àkójọpọ̀ awọn ẹbun mẹwaa ti owo wọn ko pọju ti o le ra fun awọn eeyan rẹ lasiko pọpọṣinṣin ọdun Keresimesi yii.
Mo kábàámọ̀ pé mo ṣe àtìlẹyìn fún Tinubu ní 2023, èmi gan ní ohun tó yẹ láti di ààrẹ Nàìjíríà - Seyi Makinde
Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹtàlélógún, oṣù Kejìlá ni Makinde sọ̀rọ̀ níbi àpérò tó ṣe pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn nílé ìjọba tó wà ní Agodi, Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo.










































































